Ohun gbogbo ti foju han bayii pe nitori idibo gomina to fee waye nipinle Ekiti lojo kerinla osu keje odun yii ni won se sun idibo abele egbe APC Osun siwaju.
Lati nnkan osu kan seyin ni won ti kede ojo keje osu keje yii gege bii ojo ti won yoo yan oludije ti yoo soju egbe APC ninu idibo gomina ti yoo waye lojo kejilelogun osu kesan odun yii.
Sugbon iwadi fidi re mule pe alaga apapo tuntun fegbe APC lorileede yii, Adams Oshiomole lo pase pe ki won sun ibo naa siwaju koun baa le raaye runpa-runse si oro idibo nipinle Ekiti.
Gomina tele nipinle Ekiti, Dokita Kayode Fayemi legbe oselu APC fa kale nipinle Ekiti lati kojuu Ojogbon Olusola Eleka ti egbe PDP ati awon oludije latinu awon egbe oselu to ku.
Ni bayii, o see se ko je ojo kokanlelogun osu keje ti a wa yii nidibo piramari yoo waye ninu egbe APC l'Osun, awon oludije mejidinlogbon ni won si ti fi ife han bayii lati dupo naa.
No comments:
Post a Comment