Alaimọkan eeyan nikan lo le sọ pe aṣawọ ni mi ninu oṣelu Ọṣun - Oyetọla

iroyin, oselu

Olori osise loofisi gomina ipinle Osun, Alhaji Gboyega Oyetola ti so pe oun ni gbongbo ninu oselu ipinle Osun ju opolopo awon ti won n pariwo pe ajeji loun lo.


Lasiko abewo ti Oyetola, eni to n dije funpo gomina ipinle Osun labe asia egbe APC se sawon eeyan agbegbe Iwo, Ibode-Osi, Ayedire ati bee bee lo, o salaye pe oun ni oloselu akooko to gbe boosi ti won koko lo fun egbe oselu AD nijoba ibile Boripe kale lodun 1999.

Oyetola ni ko si itan oselu nipinle Osun ti enikeni le pa fun oun nitori pe ojulowo omo egbe itesiwaju (Progressives) loun latigba toun ti bere oselu, bee ni oun n se ojuse oun bo ti ye si woodu, ijoba ibile, ijoba ipinle atijoba apapo egbe naa.

O ni aheso lasan ni pe aṣawọ tabi eni ti ko ni itan ninu oselu Osun loun ati pe ko si nnkan amuye ti enikeni nilo lati di gomina ti Olorun ko fi jinki oun.

Oyetola fi kun oro re pe oro bi awon ọdọ yoo se nise gidi lowo yoo je ijoba oun logun, bee ni ko si eni ti ko nii gbadun isejoba oun gege bii gomina toun ba lanfaani lati debe nitori pe ibi ti Gomina Aregbesola ba fi enu ọkọ isakoso gunlẹ si loun yoo ti gbe e.

O wa ro awon omo egbe oselu APC lati fi ibo won yan oun nigbakuugba ti idibo piramari ba waye gege bii oludije ti yoo soju egbe naa ninu idibo gomina ti yoo waye lojo kejilelogun osu kesan odun yii.

Oyetola seleri pe oun ko nii ja won kule, bee nipinle Osun yoo tubo goke agba labe isejoba oun.

Lara awon ti won ba Oyetola koworin lo sibi abewo naa ni Onorebu Lani Baderinwa, Alhaji Oladepo, Onorebu Ajibola Akinloye, Remi Omowaye ati bee bee lo.

No comments:

Post a Comment