Osun 2018: Awon ọdọ fariga, won ni 'West lo kan'

Se lariwo 'West lo kan' gba gbogbo igboro Osogbo kan laaro oni nigba ti ọkẹ aimọye ọdọ fọn sita, ti won n pariwo pe awon ko nii faaye gba irẹjẹ ninu idibo gomina to n bọ yii.




Awon ọdọ naa, ti won pe oruko ara won ni Osun Continuity Movement (OCM) so pe egbe oselu to ba mo pe oun fee gbapo lowo Gomina Aregbesola gbodo mu oludije lati ekun Iwo-oorun Osun.

Gege bi agbenuso egbe naa, Miftah Saheed se so, awon ekun Aaringbungbun Osun ti se gomina fun odun mokanla ataabo, bee ni ekun Ila-oorun Osun ti se gomina fun odun mejo, osu mejilelogun pere ni ekun Iwo-oorun lo nibe ri.

Miftah salaye pe egbe OCM ko sise fun enikeni bikose pe won fe ki ododo fese mule nipinle Osun, ki gbogbo eeyan si mo pe ireje lo maa n fo egbe.

O ni ko si amuye ti enikeni nilo lati di ipo gomina mu l'Osun ti awon oloselu ti won wa lati ekun Iwo oorun ko ni, won je  olopolo pipe ati eni to to fise ogun ran.

Miftah ni gbogbo awon ti oro kan nipa itesiwaju ipinle Osun lawon ti pinnu lati ba sepade lori idi ti won fi gbodo gbe gomina kale lati ekun Iwo-oorun Osun.

1 comment:

  1. Let our party,APC consider osun west and do the right thing,zone the post of governorship candidate to osun west lobatan

    ReplyDelete