Komisanna feto isuna nipinle Osun, Onorebu Bola Oyebamiji ti so pe ijoba lekajeka gbodo wa ona lati dena iru isele ina to sele nilu Eko lojo Tosde to koja lojo iwaju nitori adanu nla lo je fawon molebi to fara kaasa isele naa.
Ninu oro ibanikedun ti Oyebamiji, to tun je okan pataki lara awon oludije funpo gomina ipinle Osun labe asia egbe oselu APC fi sowo sawon oniroyin, o ni ojo manigbagbe ni ojo kejidinlogbon osu kefa je fun awon eeyan orileede yii.
Oyebamiji ni okan oun gbogbe gidi latari isele naa, oun si ba gbogbo awon molebi ti won padanu awon eeyan won sinu isele ina to sele ni Otedola Bridge, Ojodu Berger nipinle Eko kedun pupọ.
Bakan naa ni Oyebamiji gbosuba fun gbogbo awon akinkanju ti won ko ipa kan tabi omiin lati ri pe ijamba ina naa tete dawo duro.
O ni titi laelae lawon eeyan yoo maa seranti igboya ati ifaraenijin won, bee ni eleda awon ti won lanfaani lati yọ yoo maa sadura fun won.
Oyebamiji wa gbadura pe ki Olorun tu gbogbo awon ti won padanu eeyan won sinu isele ina ọhun ninu, ko si fun won lagbara lati te siwaju.
No comments:
Post a Comment