Osun 2018: Adeniji, Akinlabi, Durotoye ati Jumokol juwọ silẹ fun Ogunbiyi

Ni bayii ti idibo abele egbe oselu PDP lati mu eni ti yoo je oludije egbe naa ninu ibo gomina ipinle Osun ku ojo kan soso, awon oludije ti bere si ni juwo sile fun ara won.




Teletele, awon oludije mokanla ni won gba foomu l'Abuja lati dije sugbon won ti bere sii din ku diedie, to si se e se ki won ma ju meta lo lati dije.

Enjinia Jide Adeniji, Seneto Rasheed Akinlabi, Ojogbon Durotoye ati Seneto Felix Ogunwale la gbo pe won ti so pe awon ko dije won, won si fi atileyin won han fun Dokita Akin Ogunbiyi.

Bakan naa ni Akogun Lere Oyewumi ni tie fariwọnu ninu idije naa lati gbaruku ti Seneto Ademola Adeleke.

Awon to ku lenu e bayii ni Seneto Ademola Adeleke, Dokita Akin Ogunbiyi, Alhaji Fatai Akinbade, Onorebu Adejare Bello, Barista Oke ati Ayoade Adewopo, bee ni ko si eni to tun le so nnkan ti yoo sele ki ile oni to su.

A o ranti pe alaga egbe naa l'Osun, Soji Adagunodo ti so pe o se e se ko je pe enikansoso legbe naa yoo fa sile fundibo piramari, o si dabi eni pe oro naa n ṣẹ lo diedie bayii.

No comments:

Post a Comment