O ma se o! Igbalẹ de ọwọ Oshiomole, lo ba n yọ lẹyọkọọkan

Leyin osu kan pere ti gomina ipinle Edo tele, Comreedi Adams Oshiomole gba eeku ida gege bii alaga apapo egbe oselu APC lorileede yii, oniruuru ajalu lo ti n ja lu egbe naa.

Eleyii to buru ninu e lo sele si won laaro yii ninu eyi ti egbe naa ti pada di eyi to ni omo egbe to kere ju nile igbimo asofin agba orileede yii.

Gbogbo ogbon tijoba apapo atawon olopaa ni ni won lo laaro yii lati mase je ko se e se fun aare ile igbimo asofin lati lo sijoko ile sugbon iyen fagba han won, o ti lo ki won too de, bee ni ko seni to le fura pe o wa ninuu moto to gbe jade kuro ninu ile.

Nigba tijoko ile bere ni awon Seneto meedogun kede pe awon ti ju igbale sile, won si sa wonu egbe olonburela, iyen PDP.

Awon seneto naa niwonyii:

Sen. Tejuoso
Sen. Shaaba
Sen. Gemade
Sen. Melaye.
Sen. Shittu
Sen. Rafiu
Sen. Shitu Ubali
Sen. Isa Misau
Sen. Hunkuyi
Sen. Monsurat
Sen. Danbaba
Sen. Nafada
Sen. Nazif
Sen. Kwankwaso
Sen. Nyako

Ni bayii, awon seneto egbe oselu APC ti ku merinlelogoji, PDP je merinlelogota, APGA si ni eyokan nile igbimo asofin agba.

Iwoye opolopo awon ti won mo nipa oselu ni pe oro enu Oshiomole le sakoba fun egbe naa ti won ko ba tete wa nnkan se sii.

No comments:

Post a Comment