L'Osogbo, alubami lawon toogi APC na awon oniroyin


Eni ori yo o dile loro da laaro oni nigba tawon toogi kan ya wo ileetura GMT nilu Osogbo nibi ipade oniroyin kan to waye nibe, ti won si bere sii sina iya fawon eeyan.



Leyin ti mokanla ninu awon merindinlogun ti won je igbimo alakoso egbe oselu APC l'Osun kede pe ki alaga won, Omooba Gboyega Famodun ati akowe re, Alhaji Rasaq Salinsile loo rookun nile ni wahala ohun be sile.

Bi won se pari ipade oniroyin nibi ti oludamoran lori oro ofin fegbe naa, Barista Goke Ogunsola ti ba awon oniroyin soro lawon toogi ti gbogbo awon eeyan gbagbo pe won n sise fawon oloselu kan ninu egbe APC l'Osun ya wonu ogba naa.

Bi won se n ko koboko bo awon oniroyin, ni won n se pankere fawon agbaagba egbe ti won wa nibe, loro ba di bo o lo o ya lona.

Opolopo awon to fee fo fensi ni won farapa yannayanna, bee lawon agba obinrin n sa kijokijo kaakiri inu ogba naa, o si to ogun iseju ki ohun gbogbo to pada bo sipo.

No comments:

Post a Comment