Fun igba keji, Alhaji Fatai Akinbade yẹra fun egbe oselu PDP

Alhaji Fatai Akinade Akinbade ti kowe pe oun o se egbe oselu PDP mo.





Lasiko ti awuyewuye kan sele ninu egbe oselu PDP nipinle Osun lodun 2009 ni Alhaji Akinbade, eni to je akowe funjoba nigba naa koko binu kuro ninu egbe.

O lo si egbe oselu Labour Party nigba naa, nibe lo si ti dupo gomina lodun un 2014. Leyin naa lo pada sinu egbe oselu PDP nigba ti won lo be e.

Akinbade kopa ninu idibo abele egbe oselu PDP lopin ose to koja sugbon Seneto Ademola Adeleke lo jawe olubori.

Latari idi eyi, Akinbade, ninu atejade kan laipe yii so pe oun pinnu lati fi egbe oselu PDP sile nitori o dabi eni pe awon adari egbe naa ko fe ri oun tabi ki wiwa ninu egbe naa maa deruba won.

O ni oun gbe igbese naa leyin toun sepade pelu awon molebi, ore, ojulumo ati awon alatileyin oun ninu oselu ati pe oun ko ni enikeni ninu tabi yan enikeni lodi lori igbese oun.

Alhaji Akinbade wa dupe lowo gbogbo awon ti won nigbagbo ninu ipa isakoso re.

No comments:

Post a Comment