Ekiti 2018: Omoworare ranse ikini ku oriire si Fayemi atawon ara Ekiti


Seneto to n soju awon eeyan agbegbe Ife/Ijesa nile igbimo asofin agba orileede yii, Babajide Omoworare ti ki gomina tuntun nipinle Ekiti, Dokita Kayode Fayemi ku oriire jijawe olubori re ninu idibo to waye koja.

Omoworare, eni ti oun naa ti fi ife han lati dije funpo gomina ipinle Osun tun gbosuba fun awon eeyan ipinle Ekiti fun igbese rere ti won gbe lati da ipinle naa pada sinu egbe oselu onitesiwaju.

Ninu atejade kan ti akowe iroyin Omoworare, Tunde Dairo fi sita lo ti ni bi won se fi ibo gbe Fayemi wole yii yoo fun un lanfaani lati te siwaju ninu ise rere to n se fawon eeyan re ko too di pe won gba ijoba lowo e lodun 2014.

Omoworare ni idunnu nla lo je fun oun pe awon eeyan Ekiti fi owo ara won tun iwa won se nipa dida Fayemi pada nitori oloselu to mo ibi ti bata ti n ta awon araalu lese ni.

Bakan naa lo ki egbe oselu APC lorileede yii eleyii ti Oshiomole n dari re ku oriire aseyori nla ti won se nipinle Ekiti to je idibo akooko fawon igbimo tuntun naa. O wa ro won lati fi iru okan naa sise nibi idibo gomina to ti sunmole nipinle Osun.

Seneto Omoworare tun ro Dokita Fayemi lati sa gbogbo ipa re ninu isejoba to duroore fawon araalu, ki won le mo kedere pe iyato wa laarin ijoba to mo nnkan to n se ati ijoba alariwo.

No comments:

Post a Comment