Ohun to sele l'Ekiti fi han pe awon omo orileede yii nigbagbo kikun ninu APC - Oyetola


Okan lara awon oludije funpo gomina l'Osun, Alhaji Gboyega Oyetola ti sapejuwe esi idibo gomina to waye nipinle Ekiti lana an, ninu eyi ti Dokita Kayode Fayemi ti jawe olubori gege bii eri-maa-je-mi-niso nipa imoriri isejoba APC lorileede yii.



Oyetola ni idibo naa fi han pe awon omo orileede yii nireti to ga ninu egbe oselu APC, idi si niyen ti won fi juwọ si isejoba PDP ti Fayose n dari nipinle naa nitori won mo pe egbe APC nikan lo ni oniruuru eto amayederun fawon araalu.

Ninu oro ikinni ku oriire, eleyi ti  Dayo Fasola fowo si loruko Ileri Oluwa Campaign Organisation ni Oyetola ti ki awon eeyan ipinle Ekiti ku oriire pelu bi won se dagbere funjoba aninilara eleyii ti wahala olodun merindinlogun won lorileede yii ko tii tan nile.

Atejade naa so siwaju pe iwa adari rere tawon eeyan ri lara Fayemi lo je ki won fi ibo won gbe e wole ati pe ko nii ja awon araalu kule ninu igbekele ti won ni ninu ẹ.

Bakan naa ni won dupe lowo awon asoju kaakiri awon orileede agbaye ti won wa mojuto eto idibo naa, Ileri Oluwa si gbosuba nla fun ajo eleto idibo fun idibo alakoyawọ ti ko gbe sẹyin enikeni ti won se eleyii to ni ko seyin bi Aare Buhari se pese aabo to munadoko fun ẹmi ati dukia awon oludibo nipinle Ekiti.

Iko ipolongo Ileri Oluwa wa ro gbogbo awon ti won du ipo naa pelu Fayemi lati gbagbe ohun to ti koja, ki won si fowosowopo pelu e lati le gbe ipinle Ekiti doke tente.

No comments:

Post a Comment