Ojo Tosde ose yii, iyen ojo kerindinlogbon osu kefa odun yii ni egbe oselu Restoration Party (RP) nipinle Osun yoo seto idibo abele won lati fi mu eni ti yoo soju egbe naa ninu idibo gomina ti yoo waye lojo kejilelogun osu kesan odun yii.
Gege bi iwe ti akowe apapo egbe naa lorileede yii, Aliku Zino fi sita, meta lara awon oloye egbe RP ni egbe yoo ran wa lati sayewo awon asoju ti yoo dibo ati lati seto idibo piramari naa.
Akowe alukoro egbe naa, Kingsley DB Onuiri, adari awon obinrin, Esther Maidawa ati Oloye Nicholas B. Joshua to je adele-alaga egbe nipinle Bayelsa nireti wa pe egbe n ran bo sipinle Osun fun eto naa.
Nigba to n soro nipa imurasile won, alaga egbe RP nipinle Osun, Pasito Tosin Odeyemi ni awon meji ni won fife han lati dupo naa, laarin won naa ni awon asoju yoo ti yan enikan ti yoo je oludije.
Odeyemi ni aago mokanla aaro leto naa yoo waye ni Elsie Hotel to wa lagbegbe Alekuwodo nilu Osogbo, bee ni eto aabo to peye wa fun gbogbo awon olukopa to fi mo awon ololufe egbe Restoration Party nipinle Osun.
O ni egbe naa ko ye ninu ipinnu re lati gba ijoba lowo Gomina Aregbesola ti egbe oselu APC ati pe oniruuru eto igbayegbadun legbe naa ti seto re sile fawon eeyan ipinle Osun.
No comments:
Post a Comment