N'Ikire, irawọ Oyebamiji yọ loke tente, lariwo 'Irewọlede' ba gbagboro kan



Kekere ni gbogbo awon eeyan pe oro naa afigba ti ariwo 'Irewolede' gba gbogbo agbegbe kan, to si pada di ibudo ipolongo ibo.



Sebi ileewe awosifila tijoba Gomina Rauf Aregbesola ko ninuu Ayedaade High School to wa nilu Ikire ni minista feto eko lorileede yii, Adamu Adamu loo si lojo Monde, ojo kerindinlogbon osu kefa odun yii.

Bo tile je pe aago mokanla aaro ni won fi eto naa si, nnkan aago mejo lawon ololufe komisanna feto isuna nipinle Osun to tun je oludije funpo gomina, Ogbeni Bola Oyebamiji ti debe pelu akole orisiirisii lowo won.

Bi won se n korin ni won n jo kaakiri pe yato si pe ekun iwo-oorun Osun ni gomina kan, Oyebamiji gan an lo to si ipo naa. Se ni gbogbo nnkan sorura nigba ti Oyebamiji de inu ogba ileewe ti won ti n sayeye naa, koda, se lawon ololufe re n wo tele pelu ayo.

A oo ranti pe lose to koja lawon eeyan ijoba ibile Irewole ati Isokan lo gba foomu gomina fun Oyebamiji, won ni leyin opolopo ipade tawon se lati fi mo eni to kunju osunwon lati gbapo lowo Aregbesola lawon fimo sokan pe Oyebamiji to si ipo naa.

Gege bi okan lara awon agbaagba agbegbe naa, Alhaji Tejumade Olagunju se wi, eni to se fokantan, to si je olooto eeyan ni Oyebamiji, oke aimoye awon araalu lo si ti ran lowo pelu ipo kekere ti Gomina Aregbesola fun un, idi niyii ti won fi nigbagbo pe ti won ba fowosowopo pelu e depo nla, anfaani nla ni yoo je funpinle Osun lapapo.

Bakan naa ni Alhaji Ganiyu Oyeladun se so, o ni ko wu Oyebamiji lati dupo gomina rara sugbon gbogbo awon ti won ri amuye eni itesiwaju lara re ni won pinnu, ti won si ro o lati fi ife han si ipo naa.

Oyeladun ni eni to niteriba fun tomode-tagba, ti kii foju tenbelu enikeni, ti kii si yaju sagba ni Oyebamiji je, won si nigbagbo pe yoo te siwaju ninu awon ise ara-meriiri ti Gomina Aregbesola n se nipinle Osun.

No comments:

Post a Comment