Lasiko ti olori osise lofiisi gomina, Alhaji Gboyega Oyetola lo fibinu fi iwe sile pe oun ko se mo nitori pe Aregbesola ye adehun tawon jo se.
A gbo pe Oyetola so fun Aregbesola pe kii se oro ajoso awon ni bi Bola Oyebamiji se jade funpo gomina, ti aheso si n lo kaakiri pe owo Aregbesola wa nibe.
Sugbon bo se na faili leta ikowefiposile si Aregbe lojo Wesde la gbo pe gomina fa Oyetola lo sibikan, to si be e pe oun ko mo nnkan kan ninu bi Oyebamiji se jade.
A oo ranti pe Oyetola 'Ileri Oluwa' ni adehun aarin Aregbe ati Tinubu, sugbon nigba tawon eeyan n pariwo pe ekun Iwo-oorun lo kan ni awon omo Aregbe bere sii wa ona miin.
Laipe ni awon eeyan Ikire ati Apomu lo gba foomu fun Oyebamiji lati se gomina l'Osun, bee lawon alatileyin Aregbe bii Bola Ilori ati Basiru Ajibola bere sii sepolongo ibo fun un.
No comments:
Post a Comment