Seneto Babajide Omoworare ti ro gbogbo awon musulumi lorileede yii, paapa, nipinle Osun lati fi asiko aawe ramadan yii gbadura fun alaafia orileede yii.
Ninu oro ikinni ti seneto to n soju awon eeyan agbegbe Ife/Ijesa naa fi ranse sawon musulumi lo ti ro won lati fi asiko aawe yii jin fun isipe lodo Olorun fun alaafia ati isokan orileede Naiiria.
Omoworare so pelu idaniloju pe egbe oselu APC lorileede yii ati nipinle Osun nigbagbo pupo ninu adura awon olododo eleyii ti won yoo maa gba si Olorun lasiko ifaraenijin yii.
O ni isipe nikan pelu igbagbo lo le ranjoba Ogbeni Aregbesola lowo lati se aseyori ninu awon ise iyipada to n se lowo nipinle Osun.
Bakan naa ni asaaju kan ninu egbe oselu APC nipinle Osun, Alagba Peter Adebayo Babalola ro awon musulumi lati rii daju pe iwa ati ise Ojise nla Mohamed farahan ninu igbesi aye won lasiko aawe yii.
Babalola ninu atejade kan to fowosi salaye pe asiko to se pataki ninu igbesi aye awon musulumi ni asiko aawe je, won si gbodo gbe igbe aye iwa mimo lati le je ki aawe naa setewogba.
O waa ro won lati ke pe Olorun fun ijoba rere nipinle Osun eleyii ti yoo te siwaju ninu ise rere Ogbeni Aregbesola ni bayii tidibo gomina ti n kanlekun nipinle Osun.
No comments:
Post a Comment