Aisan okan pa oludije funpo gomina nipinle Ekiti




Barista Kole Ajayi, eni to je okan lara awon oludije funpo gomina ipinle Ekiti lodun un 2014 ninu egbe oselu Accord Party ti jade laye laaro oni.


Loju ona Ekiti si Eko la gbo pe aisan okan ti ki okunrin oloselu yii mole, ki won si too gbe e deleewosan lo ti jade laye.
Ipa takuntakun la gbo pe Ajayi, eni ti inagije re n je “Abere mi lokun nidi” n ko latigba to ti darapo mo egbe oselu APC, koda, o duro wamuwamu lojo kerinla osu yii nibi idibo abele egbe oselu APC to gbe Dokita Fayemi wole.
Koda, laaro oni lokunrin naa soko oro ranse si Gomina Fayose lori ero ayelujara.
Ohun to so niyii “Where was America when Koro, Tko, Omisore, Oshoko and Captain Koli invaded Ekiti with Military to scuttle our people’s will?Gba fun gbada nile ni gbafun gbada loko.He who seeks equity must come in clean hands.JKF ti daraba!!Let’s go there”.

No comments:

Post a Comment