Omisore o tii so fun wa pe oun ti kuro ninu egbe oselu PDP - Adagunodo

Alaga egbe oselu PDP nipinle Osun, Onorebu Soji Adagunodo ti so pe aheso lasan lo si je lodo egbe oun pe Seneto Iyiola Omisore ti kuro ninu egbe naa.




Nibi ipade oniroyin to se laipe yii ni Adagunodo ti ni eni to niriri ninu oselu bii Seneto Omisore gbodo mo pe o pon dandan keeyan kowe fegbe sile to ba fee kuro ninu egbe.
O ni omo egbe oselu PDP si ni Omisore niwon igba ti ko tii kowe fipo sile gege bii omo egbe, bee laaye si wa fun un lati dije ninu egbe naa.
Gege bo se wi, ' Seneto Omisore o tii so fun wa pe oun fee fi egbe PDP sile, a ko tii ri leta re, okan lara awon asaaju egbe wa ni, o lanfaani lati dije pelu awon oludije to ku, ko saaye pe ki enikan ro pe oun nikan loun yoo dije, ilekun si fun gbogbo oludije ni".

No comments:

Post a Comment