Osunwon Omoluabi ti fopin si iyanje ninu eto karakata l'Osun - Babaloja

Babaloja funpinle Osun, Oloye David Iyiola ti so pe ipa takuntakun ni Osunwon Omoluabi tijoba ipinle Osun sagbekale re n ko bayii lori oro karakata kaakiri awon oja.



Lasiko eto itaniji lorii pataki lilo Osunwon Omoluabi, eleyii to waye ninu oja Igbona nilu Osogbo  ni Oloye Iyiola ti ni ko si anfaani iyanje mo laarin awon onraja ati ontaja.

Baba yii gboriyin fun Gomina Aregbesọla fun ogbon inu to fi seto osunwon naa nitori pe ija ojoojúmọ́ to maa n waye laarin awon onraja ati ontaja latari iyanje to wa ninuu kobiowu ti rokun ìgbàgbé bayii.

O waa fi da ijoba loju pe gbogbo awon oloja kaakiri korokondu ipinle Osun ni won yoo bere sii lo Osunwon naa nitori anfaani pupo lo wa nibe.

Komisanna foro okoowo, ileese nlanla ati alajeseku nipinle Osun, Adekunle Jayeoba-Alagbada so pe aseyori nla ni agbekale osunwon Omoluabi naa je funjoba Aregbesọla.

O waa fi da gbogbo awon oloja kaakiri awon Ipinle to yi ipinle Osun ka loju pe ko lee si iyanje ninu oja ti won ba ra tabi ti won ba gbe wa si Osun fun tita.

Oludamoran pataki fun Gomina Aregbesọla lori oro okoowo, Onorebu Femi Popoola ṣalaye pe oja mejidinlaadota lawon ti gbe eto itaniji naa lo nipinle Osun ati pe enikeni ti ko ba faaye gba lilo osunwon naa yoo ri pipon oju ijoba.

No comments:

Post a Comment