Agba ofifo lasan ni Ojo Williams ati Bade Falade ninu oselu - PDP Osun


Egbe oselu PDP nipinle Osun ti ni kikuro ti oludamoran lori oro ofin fun egbe naa niha Guusu Iwo-orun orileede yii, Barista Sunday Ojo Williams kuro ninu egbe naa ko lee tu irun kankan lara aseyori egbe naa nipinle Osun.



Bakan naa ni won sapejuwe lilọ Onorebu Bade Falade bii ofuutufeete nitori 'ko si oore kankan ti won n se fun egbe nigba ti won wa nibe'.
Lasiko ti alukoro egbe naa l'Osun, Sunday Bisi n fesi si bi awon eeyan mejeeji naa ti won je alatileyin Seneto Iyiola Omisore se so lana an pe awon ti fi egbe oselu PDP sile lo ti ni laala awon eeyan miin ti won nitumo ninu egbe lawon mejeeji maa n je latigba ti idibo ti n waye l'Osun.
Onorebu Bisi ni "ko si idibo kankan ti a se ti eyikeyi ninuu won rowomu nibudo idibo won ka too waa so woodu won. Nigba ti won ti rii pe egbe wa ti kuro legbee 'sise koro, jije ofe' lo mu won sa kuro bayii.
"Mo waa layo lati so fun gbogbo awon eeyan ipinle Osun pe lilo awon eeyan yii gan an lo maa silekun sile fun opolopo awon omo egbe oselu APC ti won fee darapọ mo egbe PDP latijoba ibile tawon mejeeji ti wa nitori opolopo lo n binu nitorii tiwon gan an tele".

No comments:

Post a Comment