Aregbesọla yoo bere abewo asekagba kaakiri ipinle Osun lose to n bo
Lara igbese to kangun si imurasile fun eto idibo gomina ipinle Osun ti yoo waye losu kesan odun yii, Gomina Aregbesola yoo bere abewo kaakiri awon ekun ijoba apapo meseesan to wa nipinle Osun lose to n bo.
Iwadi Agbala Iroyin fidi re mule pe Aregbesọla yoo lo asiko naa lati jabo ise iriju re lati odun meje ataabo seyin to ti n tuko ipinle Osun fawon eeyan agbegbe to n lo, bakan naa lawon araalu yoo tun lanfaani lati beere ibeere ati lati so edun okan won fun gomina.
Leyin ipade ita-gbangba yii la gbo pe o see se ki egbe oselu APC si ilekun sile fun enikeni to ba fee dije ninu idibo naa.
Ni bayii, atejade lati odo alukoro fegbe oselu APC l'Osun, Kunle Oyatomi je ko di mimo pe ojo Monde, ojo ketalelogun osu kerin odun yii si ojo kerin osu karun odun yii labewo naa yoo fi waye.
Lati Ileefe ti eto naa yoo ti bere ni yoo ti koja si Ijebu Ijesa, si Ikirun, ko too kan Ila, koja si Ede, Ikire, ko too wa pari si Iwo.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment