N'Ipetumodu, owo te Wale, okan lara awon adigunjale to fo banki l'Offa

Owo awon olopaa ti won n sewadi awon adigunjale to sose nilu Offa lose meji seyin ti te okan lara awon eeyan ohun nilu Ipetumodu nipinle Osun.



A gbo pe leyin isele naa, ninu eyi ti eeyan bii ogoji to fi mo awon olopa ti ku ni Wale ti pada silu Ipetumodu nibi to gbale si pelu orebinrin re toun je akekoo ile eko giga kan to wa nilu yen.

Lojoru to koja la gbo pe awon olopa naa pe foonu enikan to dabi eni pe Wale maa n pe ju, leyin ti won mu eni naa ni won ni ko mu awon lo sibi ti Wale le wa.

Ko pe naa ni won rii nibi to ti fe ra nnkan, kia ni won yinbon fun lesẹ ko ma baa salo, leyin eyi ni won loo mu orebinrin re, ti won si ti ko won lo bayii.

No comments:

Post a Comment