Iroyin to n te wa lowo bayii ti fi han pe ori afara kan nilu Abuja lawon ero-oju ona ti ri opa ase ileegbimo asofin agba ti awon janduku kan loo gbe lana.
Gege bi ASP Aremu Adeniran to je Igbakeji alukooro funleese olopa lorileede yii se so, lori afara kan to wa nitosi Abuja City Gate lawon to n koja ti ri ọpa ase naa, ti won si ta ileese olopa lolobo.
A oo ranti pe losan ana lawon janduku eleyii ti Seneto Ovie Omo Agege ti won ni ko lo rookun nile laipe yii ko sodi ya wonu ile igbimo asofin agba lasiko ti ijoko ile n lo lowo, ti won si gbe opa ase naa lo leyin ti won se opolopo eeyan lese tan.
No comments:
Post a Comment