Oluwo tilu Iwo, Oba Adewale Akanbi ti so gbangba pe ko si ilu ti itan re pe lorileede yii laidaruko Ooni.
Lasiko ipade awon lobaloba to waye laafin Ooni nilu Ileefe ni Oluwo ti soro naa.
O ni Ooni ni baba gbogbo oriade nitoripe lodoo re ni gbogbo won ti gba ade ti won n de.
Oluwo ni lati ile Yoruba, titi de ile Hausa ati ile Yibo, Ooni kii se eni arifin rara.
Ninu oro tire, Ooni ti ilu Ileefe, Oba Enitan Ogunwusi so pe ko si wahala kankan laarin awon oba nipinle Osun ati pe Oluwo lawon mo Oba Akanbi si kii se Emir.
No comments:
Post a Comment