Onisekuse: Won lo ti pe ti Ojogbon Akindele ti n jeran 'sunkunsi' awon akeko OAU

Bo tile je pe awon alase ileewe Obafemi Awolowo University ni Ileefe ti gbe igbimo kan dide lati sewadi Ojogbon Richard Akindele ti won fesun kan pe o n beere ibalopo eemarun lowo akekobinrin kan lati gba maaki, sibe, asiri miin tun ti fojulede lori iwa okunrin naa.




Lagbara iroyin lo ti te wa lowo pe o ti le ni ogun odun ti ojogbon to n pe araa re niranse Olorun yii ti maa n fi isekuse lo awon akekobinrin lọgba OAU.

Gege bi akekojade kan leka isiro owo nileewe naa se so lorii feesibuuku, o ni ojogbon yii kannaa lo wo mọ oun ni nnkan ogun odun seyin toun wa nileewe ati pe Olorun nìkan lo ko oun yo lowo e.

Obinrin to ti wa lorileede Ireland bayii ni se ni Ojogbon yii maa n so awon omobinrin ti won ba ni wahala kan tabi omiin, tí yoo si maa hale mo won pe afi ti oun ba ni ibalopo peluu won loro won too le lojutu ninu ogba.

A oo ranti pe ori intaneeti lomobinrin akeko kan ni OAU gbe itakuroso laarin re ati Ojogbon Akindele si nibi ti oluko yii ti n beere fun ibalopo eemarun koun le fun un ni maaki mefa to nilo lati kogoja.

No comments:

Post a Comment