Abenugan tele funle igbimo asofin Ipinle Osun, Onorebu Adejare Bello ti ni isejoba Gomina Aregbesola lo ye ko je eyi ti yoo se daada julo l'Osun sugbon orikunkun ati aigba imoran lo ba ti isejoba naa je.
Lasiko to loo fi erongba re han fawon asaaju egbe PDP l'Osun pe oun nife dupo gomina ti yoo waye l'Osun lojo kejilelogun osu kesan odun yii ni Adejare ti ni mo-gbon-tan mo-mo-tan lo n ba Aregbesola ja, eleyii to mu kisejoba re ni awon araalu lara.
O ni bo tile je pe owo to din ni bilioonu meji naira nijoba Omooba Oyinlola n gba latodo ijoba apapo nigba naa, sibe nigba ti oro ekunwo owo osu awon osise de, ti Oyinlola so pe oun ko nii da sii, nigba tawon osise mu oro naa wa ba oun, oun ba Oyinlola soro, o si gba si oun lenu.
O fi kun oro re pe adari ti yoo se gba nimoran loun yoo je, bee ni oun yoo bu ola to to fawon agbaagba egbe nipa jije ki won mo si nnkan to ba n lo ninu isejoba loorekoore ti won ba le gbe oun sile gege bii oludije lasiko ibo naa.
Adejare, eni ti ogunlogo awon alatileyin re ba koworin lo si olu ile egbe PDP salaye pe iriri oun labe isejoba awon Gomina meta otooto ti je koun mo nipa isejoba ipinle Osun daadaa eleyii ti yoo si ran oun lowo pupo lati saseyori si rere.
Ninu oro re, alaga egbe oselu PDP l'Osun, Onorebu Soji Adagunodo ki Adejare Bello ku ise. O waa seleri pe ko nii si ojusaju nipa oludije ti won yoo fa kale ati pe egbe ko nii yan enikeni niposin laarin gbogbo awon ti won ba fife han lati dije.
No comments:
Post a Comment