Ni bayii tawon alatileyin Otunba Iyiola Omisore ti kede pe awon ti fi egbe oselu PDP sile nipinle Osun, eni to je adari won, Dokita Bayo Faforijin ti je ko di mimo pe kosu yii to pari, won yoo kede egbe oselu ti won yoo darapo mo.
Lasiko ipade kan ti won se nile egbe PDP to wa loju ona Ogo-Oluwa nilu Oṣogbo ni won ti so pe niwon igba ti ko ti si ibowo fun ofin egbe ninu PDP mo, awon fi egbe sile fawon Adagunodo.
Faforijin ṣalaye fun Agbala Iroyin pe gbogbo awon ololufe Omisore lawon so fun un pe ko kuro ninu egbe PDP lati le loo dije funpo Gomina ipinle Osun ninu egbe oselu miin.
O fi kun oro re pe pelu ami tawon n ri bayii, ojusaju yoo wa ninu ibo abele lati yan oludije egbe PDP l'Osun, idi si niyen tawon fi tete fi egbe sile fun awon ti ko nibowo fegbe.
No comments:
Post a Comment