Nnkan nla! Aregbesọla ni kawon oniroyin lo maa mẹfun
Aheso lawon eeyan koko ka oro naa kun, afi igba ti iwe jade lati ofiisi olori awon osise ijoba nipinle Osun, Dokita Olowogboyega ninu eyi to ti pase pe ki awon oniroyin kan maa lo sileewe gege bii oluko.
Ninu iwe naa ni Olowogboyega ti ni ase naa wa nibamu pelu erongba ijoba Aregbesọla lati mu atunto ba eto eko nipinle Osun.
Ohun to waa se awon eeyan ni kayeefi nibe ni pe awon sanko-sanko ti oro yii kan lo je pe won ti n sise iroyin lati nnkan ogun odun o le seyin.
Lara won ni alaga egbe oniroyin l'Osun, Motunrayo Ayegbayo, alaga egbe akoroyin ere idaraya l'Osun, Adeyemi Aboderin, Abosede Oyegbade ati bee bee lo.
Atejade ohun ni won ti ni ki Ayegbayo maa lo sileewe Oṣogbo High School won si gbe Aboderin lo sileewe kan lagbegbe Ota-Efun.
Ibeere awon araalu ni pe lai lo ojo kan ri ni kilaasi gege bii oluko, bawo lawon eeyan naa se fee mo ohun ti won yoo ko akekoo? Iwadi si tun fi han pe oro naa lowo kan oselu ninu eleyii ti a maa fi to yin leti laipe
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment