Erejẹ ijọba tiwantiwa: Ayo Omidiran pin ogorun naira fawon ara Ikire


Bii fiimu lo ri lopin ose to koja nigba ti asofin to n soju awon eeyan agbegbe Irewole/Isokan/Ayedaade nile igbimọ asofin apapo orilẹede yii, Onorebu Ayo Omidiran bere sii pin ogorun naira fawon eeyan ilu Ikire.



Ayeye kan la gbo pe won pe Omidiran, eni to ti figba kan je ana Gomina Aregbesọla si, bo si se debe lawon omode ati odo pon on le, idi niyen to fi ni ki won to bi won se ga si, to si bere sii ha ogorun naira le won lowo.
Oju ọtọọtọ lawon ti won wa nibe lojo naa fi wo iwa ti obinrin yii hu. Bi awon kan se n so pe ko si nnkan to buru ninu ohun to se lawon miin ni aponle tawon omo yen fun un lojo naa ju owo to ha le won lowo lo to ba je pe oloselu to nitiju ni.

No comments:

Post a Comment