Ko si agbara ti oludibo ni laisi kaadi idibo - AGF
Egbe Asiwaju Grassroot Foundation (AGF) ti so pe ẹnikẹni ti ko ba fe ki won fi eto re du lasiko idibo gomina to n bo lona l'Osun gbodo loo forukosile fun kaadi idibo.
Ninu atejade kan ti alaga egbe naa, Comredi Sikiru Tijani ati akowe, Comreedi Yahaya Adeniji fi sita ṣalaye pe anfaani nla ni olude ti Gomina Aregbesola fi sile je eleyii ti gbogbo eeyan gbodo lo daada.
AGF ni fun ijoba tiwantiwa lati lagbara ati lati te siwaju lorileede yii, gbogbo araalu gbodo forukosile ki won si gba kaadi idibo.
Atejade naa fi kun un pe gbogbo awon ti won ti to ojo-ori lati dibo gbodo jade loo gba kaadi idibo, awon ti won si ti so kaadi idibo won nu gbodo loo gba kaadi miin ti won ba mo pe awon fee dibo yan gomina ti won fe losu kesan odun yii.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment