Ko le si ilosiwaju kankan lorileede yii afi ki Buhari loo sinmi nile - Omooba Fadahunsi


Omooba Francis Adenigba Fadahunsi ti so pe ko si itesiwaju kankan to le ba orileede Naijiria labe isejoba Aare Buhari afi ki awon eeyan je ko loo sinmi nile.



Fadahunsi, eni to je asaaju kan ninu egbe oselu PDP l'Osun ṣalaye pe ẹmi Buhari n fe ko se daada sugbon ko ni agbara lati se e.

Lasiko to n gba awon oniroyin lalejo nilu re, Ilase Ijesa gege bii ara ayeye odun awon oniroyin nipinle Osun ni Fadahunsi so pe ipa ti pin fun Buhari, gbogbo nnkan ti agbara re si gbe lo ti se forileede yii.

O ni afi ki awon omo orileede yii faaye gba Buhari lati loo sinmi nile nitori agbara re ko ka oro eeto aabo ile yii eleyii to n fojoojumo ran kale bii osumare.

Fadahunsi ni oro eto aabo orileede yii ko buru to bayii ko too di pe Buhari de ori aleefa, bee ni ko ri ojutuu sii lati odun meta to ti debe eleyii to tumo si pe ajalu yii yoo tun maa tesiwaju lọdun merin miin ti won ba tun dibo yan an.

O ni egbe oselu PDP nikan lo le gba orileede yii kale ninuu laluri to wa yii, bee lo ro awon araalu lati fi ibo won le egbe APC lo, ki won si gbe egbe PDP wole.

No comments:

Post a Comment