Oloba ti Oba-Ile, Oba Oyeyemi fee sayeye odun kan lori ite


Oniruuru eto lo ti wa nile lati fi sayeye odun kan ti Oba Adekunle Asamu Oyeyemi tii se Oloba ti Oba Ile nijoba ibile Olorunda nipinle Osun gun ori ite awon babanla re.



Gege bii atejade kan lati odo igbimọ ayeye naa se salaye, won yoo foye da awon lookolooko lola, bee ni won yoo sedasile eto ikowojo fawon omobibi ilu naa ti won lopolo pipe sugbon ti ko si oluranlowo lati ran won nileewe.

A oo ranti pe ojo kinni osu kinni odun 2017 nijoba ipinle Osun kede oruko Oba Adekunle leyin tawon afobaje ilu naa se ohun gbogbo to to lori e, tijoba si gbe opa ase fun un lojo keje osu kerin odun naa.

Gege bi awon igbimo ohun se wi, ojo kerinla osu kerin odun yii leto naa yoo bere pelu awon oniruuru ayeye ti won ti la sile.

Won yoo fi oye Asiwaju ati Yeye Asiwaju da Oloye ati Iyaafin Samuel Olu Alabi lola ni imoriri ipa ti won ti ko lori idagbasoke ilu Oba.

Bakan naa ni Oloye ati Iyaafin Chris Seyinde Ogunrinde ti won je onisegun oyinbo ti won fi orileede Canada sebudo yoo je oye Otunba Atobase ati Yeye Oloba ti Oba-Ile, nigba ti Oloye Adedotun Ajala latilu Ilorin yoo je Bobajiro ti Oba-Ile.

Orii papa ileewe Aderounmu Grammar School, Oba-Ile ni asekagba eto naa yoo ti waye labe alaga His imperial Majesty, Alayeluwa Oba Adeyeye Enitan Ogunwusi, Ojaja II, Ooni ti Ife.

Nibe ni won yoo tun ti sefilole OBA-ILE EDUCATION ENDOWMENT TRUST FUNDS fawon omobibi ilu naa ti ko si iranlowo lati kawe.

No comments:

Post a Comment