E je ka samulo eko to wa ninu Ajinde Jesu - EAF
Ti gbogbo kristieni ba fee tele ilana bibeli nipa igbesi aye Jesu, a gbodo mu igbe aye ififunni lokunkundun.
Eleyii ni oro odun ajinde ti oludasile ijo Love of Christ Generation Church, UK, Revd Mother Esther Ajayi fi sita.
Ajayi, eni to tun je Alakoso ajo Esther Ajayi Foundation to n saanu fawon eeyan lorisiirisii so pe Iku ati ajinde Jesu kii se nipa awejewemu nikan bikose nipa sise aanu gege bo se farahan ninu igbe aye Kristi.
O ni ko tun si ife kankan to lagbara to eyi ti Jesu safihan re nipa iku ori igi agbelebu, idi niyen to fi pon dandan fun gbogbo kristeni lati maa fifun awon alaini nigba to wọ ati igba ti ko wo.
O ni gbogbo eeyan gbodo lo asiko yii lato nawo ife si awon alaini lati le je kawon naa ni imolara iku ati ajinde Jesu ati lato le mu ki aye rorun fawon to ku die kaa to lati gbe.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment