Leyin wakati merinlelogun ti Oluwo tilu Iwo, Oba Abdulrasheed Adewale Akanbi so pe oun ko fe ki won maa pe oun ni Oba ti ilu Iwo mo bikose Emir ti ilu Iwo, Oba Akanbi ti yi ohun pada bayii, o ni kii se nnkan toun so niyen.
Eleyii ko seyin bi awon omo Yoruba se gboju aagan si oro to ti enu oba naa jade, ti awon eeyan si ti n koraa won jo lati pe fun iyonipo oba naa niwon igba to je pe Oba Iwo lo ni ori-ite to wa, kii se Emir ti Iwo.
Nibi ayeye ifijoye Waziri ti ile Yoruba ti Oluwo fi enikan je lojoo satide to koja, lainaani ikilo awon agbaagba musulumi lori oye naa, lo ti so pe rikisi ti po ju laarin awon oba ile Yoruba, idi niyen toun fi pinnu lati maa ba awon fulani darandaran lo.
Sugbon kia lawon eeyan bere sii soro kobakungbe si oba naa ninu iwe iroyin, lori itakun ayelujara ati bee bee lo.
Idi niyii ti akowe iroyin Oluwo fi ke gbajare sita pe se ni won si oba naa gbo, o ni ohun ti Oluwo so ni pe oun naa, gege bii oba ilu ti esin Islam ti dun awon eeyan lara le maa je Emir, kii se pe oun ti n je Emir o.
No comments:
Post a Comment