Gege bii ajinde Jesu, ireti si wa fun wa nipinle Osun - Enjinia Jide Adeniji
Alaga ajo to n mojuto atunse awon oju ona ijoba apapo tele, Enjinia Jide Adeniji ti so pe bo tile nira fun opolopo awon eeyan nipinle Osun lati se odun ajinde bi okan won se fe latari eto oro aje to denukole, sibe, agbara to ji Jesu dide kuro ninu oku si le mu ohun gbogbo bo sipo.
Ninu oro odun ajinde ti Adeniji fowo si lo ti ni imupadabosipo naa ko lee seyin bi awon eeyan ipinle Osun ba pinnu lokan ara won lati dibo yan eni ti yoo fun won lojo iwaju rere lasiko idibo gomina to n bo ninu osu kesan odun yii.
Asiwaju ninu egbe oselu PDP, to tun je okan lara awon to n fojusona lati dije funpo gomina ohun fi kun oro re pe loooto lopolopo omo alaso ti n wo akisa l'Osun bayii, sugbon niwon igba ti ajinde Jesu ti mu ireti ba awon kristiani, imole yoo tan leyin okunkun to su lowolowo bayii nipinle Osun.
Adeniji ni owo awon araalu loro naa wa, o salaye pe onikaluku to ti to lati dibo gbodo loo gba kaadi idibo won, ki won si toju e daada de asiko idibo.
O ro awon araalu lati mase ta ojo-ola won nipa titori owo ti ko to nnkan dibo fawon ojelu, sugbon ki won mo pe ọwọ araa won ni won fi le tun nnkan se funpinle Osun.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment