Loooto ni ipenija wa po lorileede yii, sibe, agbara Olorun ka gbogbo e - Aregbesola

Gomina Rauf Aregbesola ti ro gbogbo awon eeyan ipinle Osun, laifi ti esin tabi eya se, lati fi asiko ayeye odun ajinde yii gbadura si Olorun nipa orileede yii. 



Ninu oro ikinni odun ajinde ti oludamoran lori eto iroyin fun Gomina, Sola Fasure fi sita ni Aregbesola ti ṣalaye pd ife to farahan ninuu irubo ni ajinde Jesu n sapere, idi niyii ti tolori-telemu fi gbodo fi ife han si alaafia ipinle Osun ati orileede Naijiria.

O ni ife lo mu ki Jesu farada iya ati esin, titi de oju iku ko too wa ni isegun lori iku, idi niyii to fi se pataki ki gbogbo onigbagbo fiwa jo Kristi ninu ife ati ipamora.

Aregbesola ni 'nibi ti ko ba si ife ni oniruuru iwa ipa maa n gbe, eni to ba feran omonikeji re ko ni maa jale, ja tabi paayan, kristiani to ba fee gbe igbe aye to pe gbodo ni ife gege bii Kristi".

O waa pe fun igbagbo kikun ninu orileede yii ati adura igba gbogbo laika oniruuru awon ipenija to n koju re lowolowo nitori pe owo ati agbara Olorun ka won.

No comments:

Post a Comment