Ko tii si iru oloselu bii Asiwaju Bola Tinubu lorileede yii - Omowoare


Seneto to n soju awon eeyan agbegbe Ife/Ijesa nile Igbimo asofin agba, Babajide Omoworare ti sapejuwe adari apapo fegbe oselu APC, to tun je Gomina tele nipinle Eko, Asiwaju Bola Ahmed Tinubu gege bi oloselu ti igbe aye ifaraenijin re yato gedengbe ninu itan oselu orileede Naijiria.


Ninu atejade kan ti akowe iroyin fun seneto yii, Tunde Dairo fi sita lati ki Tinubu ku oriire ajodun odun kerindinlaadorin to dori eepe ni Omoworare ti ni Tinubu je oloselu ti ko mo tara re nikan, to si maa n fi gbogbo igba wa nnkan to le mu ki aye rorun fun enikeni to ba sunmo on.

O ni igbe aye ifaraenijin lo so Tinubu di awokose rere laarin awon oloselu lorileede yii ,to si je pe kaakiri ni won maa n bu ola to ye fun un nitori ipa to ti ko ninu aye opolopo awon oloselu asiko yii.

Omoworare ni ti Tinubu ba ran enikeni nise, se lo tun maa fowo tii leyin, ti yoo si setan lati fun onitohun ni ohunkohun ti yoo mu saseyori lenu ise naa.

Seneto yii waa gbadura emi gigun ati alaafia fun Asiwaju Tinubu, bee lo ni erongba rere ti Tinubu ni fun orileede yii yoo wa simuse loju emi e.

No comments:

Post a Comment