Egbe oselu Restoration Party (RP) nipinle Osun ti so pe awon ti setan lati mu ohun gbogbo bo sipo fun elekajeka niwon igba ti won ba ti le fi ibo won gbe oludije egbe naa wole gege bii gomina lasiko idibo osu kesan odun yii.
Alaga egbe naa l'Osun, Comredi Tosin Odeyemi lo soro yii fun Agbala Iroyin. O ni bo tile je pe egbe naa sese gba iwe eri latodo ajo INEC ni, sibe, awon wa nimurasile lati yo awon eeyan ipinle Osun lofin ti egbe oselu APC fi won si.
Odeyemi ni egbe naa je itewogba kaakiri awon ijoba ibile to wa l'Osun latari ijakule tawon eeyan ti ba pade ninu egbe oselu PDP ati APC.
O seleri pe ohun gbogbo yoo pada bo sipo nipinle Osun nitori awon eto meremere legbe naa ni nipamo fawon araalu, ati pe won yoo gbagbe iya to ti je won ni kete ti egbe naa ba gbajoba lowo Aregbesọla.
Alaga yii so siwaju pe awon yoo te siwaju ninu awon nnkan to nitumo tijoba Aregbesola n se sugbon gbogbo awon ona tijoba naa n gba farani awon araalu legbe Restoration Party yoo wa ojutu si.
O waa ro gbogbo awon ti won ti to lati dibo lati yara loo gba kaadi idibo won ki asiko too to nitori itan rere ni yoo je ti gbogbo eeyan ba le fowosowopo gbajoba lowo egbe APC fun egbe Restoration Party nipinle Osun lọdun yii.
Olu ile egbe Restoration Party wa ni 906a, Gbongan Ibadan road, nidojuko ileepo NIPCO filling station nilu Osogbo. Bee le le kan si alaga ati akowe egbe nipinle Osun lori awon nomba wonyii: 0818573605 ati 08085258963.
No comments:
Post a Comment