Won ni Akeem pa Sajenti Opeyemi iyawo re, o ti n se faaji lewon bayi
Adajo kootu kan nilu Oṣogbo ti pase pe ki won lo fi Abiodun Akeem Oladebo pamo sogba ewon titi ti imoran yoo fi wa lati ileese eto idajo ipinle Osun lori esun ti won fi kan an.
Se lawon olopa so pe Akeem, omo odun mokanlelogoji lo pa iyawo re, Sajenti Opeyemi Ojo lojo keedogbon osu keji odun yii.
Inspekito Tajudeen Mustapha so funle ejo pe se ni Akeem so ori obinrin olopa yi mo ogiri, eleyi to yori si iku ojiji to ku. O ni iwa naa nijiya labe ofin iwa odaran tipinle Osun.
Mrs B Y. Dada to duro fun olujejo ro ile ejo lati je koun gba beeli re sugbon Onidajo Ajanaku ni rara, afi ki won lo fi pamo sogba ewon.
O wa sun igbejo siwaju di ojo kesan osu karun odun yi.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment