E waa wo Simia to pa oree re l'Osogbo o
Medinat Adesoye
Ile ejo majisreeti ti o tedo si ilu Osogbo ti ni ki arabinrin kan ti oruko re n je Jimoh simiat lo ma gba afefe logba ewon lori esun pe o pa Mama Friday ti won ri oku re ni Oke Osun nilu Oṣogbo.
Inspekito Mustapha Tajudeen to soju ileese olopa ṣalaye pe lojo kewa osu keji, odun yii ni deede ago meje abo owuro ni agbegbe ile iwe giga Fountain university, ni ilu osogbo ni Simiatu ba Esther Oga to je ore re ja titi ti emi fi bo lenu e.
Inspekito naa so pe afurasi naa ti se lodi si abala 316, ti o si le fi iya je ni abala 319(1), ofin iwa odaran ipinle osun ti odun 2002.
Nigba ti adajo kootu beere oro lowoo Simiatu, o lojo kesan osu keji odun yii ni oun loo ba ologbe naa ni ile lati beere pe se loooto lo so fun oko re, iyen Baba Friday pe olosho ni oun, ti Baba Friday naa si tun so oro naa fun oko toun.
Simiatu ni oro naa lawon loo yanju nidi ogede lojo naa, tawon si tuka.
Ninu idajo Adajọ majisreeti naa, Tunde Badmus so pe ile ejo majisreeti o ni ase lati gbo iru ejo naa, o ni ki afurasi naa wa ni ogba ewon titi di ojo ti won sun igbejo naa si.
Adajo sun igbejo naa di ojo kejo osu karun, odun ti a wa yii.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment