Medinat Adesoye, Osogbo
Diran Olawale ti won fesun kan pe o lu Abiola Adelakun ni jibiti owo to din die ni milionu kan naira ti foju bale ejo bayii.
Gege bi Sajenti Adewuyi Kehinde se so nile ejo, o ni ni igba kan ninu osu kerin, odun 2011, ni adugbo Olobi, Owoope nilu Osogbo, olujejo gba owo lati ba Ogbeni Abiola Adelakun ra eeka ile marun, eleyii to si pada ja si iro.
Sugbon olujejo so funle ejo pe oun ko jebi gbogbo esun ti won fi kan oun, bee ni agbejoro re ro ile ejo lati fun un ni beeli ti o rorun, o si se ileri pe oniduro gidi ni olujejo naa maa muwa.
Adajo O. A Oloyade fun olujejo naa ni beeli pelu egberun lona eedegbeta naira, oniduro meji ti won gbodo ni iwe eri odun meta ti o fihan pe won san owo ori re.
Adajo waa sun igbejo siwaju di ojo keta osu karun, odun yii.
No comments:
Post a Comment