Medinat Adesoye, Osogbo
Leyin nnkan bii ojo merinlelogoji ti awon omo iko Boko Haramu ya wonu ileewe giga kan to wa ni Dapchi nipinle Yobe, ti won si ko awon omo marunlelogorun lo, iroyin ayo ti a gbo bayii ni pe won ti da awon omo ohun pada.
Bo tile je pe marun la gbo pe o ti ku lara awon omo naa, sibe, senken ni inu awon eeyan ilu naa n dun nigba ti won dede rii ti awon Boko Haram da awon omo naa sile latinu moto nla ti won fi ko won lo saarin ilu.
No comments:
Post a Comment