Owo te Odesola to fee fomo re soogun owo l'Osun

Medinat Adesoye

Owo ileese olopa ipinle Osun ti te okunrin eni odun mejidinlogoji kan, Odesola Odedokun lori esun pe o fee fi omo re, Mary soogun owo.




Odesola ni owo te pelu awon meji miin, Isaac Ojo ati Kazeem Ibrahim lojo keje osu keta odun yii ni nnkan aago meje aabo irole nilu Ifon Osun nipinle Osun.

Inspekito Mustapha Tajudeen to n soju ileese olopa lori oro naa salaye pe Ibrahim tun gba owo lowo Isaac pe oun yoo ba so owo naa di pupo.

Agbejoro fawon olujejo, Ngwu ro ile ejo lati faye beeli sile fun won.

Onidajo F.A. Sodamade gba beeli okookan won pelu egberun lona eedegbeta naira ati oniduro kookan to gbodo wa nipele keedogun owo osu gege bi osise ijoba.

O wa sun igbejo siwaju di ogbonjo osu kerin odun yii.

No comments:

Post a Comment