Alaimoore eeyan nikan lo le so pe ijoba PDP dara ju ti APC lo l'Osun - Oyatomi

Alukooro fun egbe oselu APC nipinle Osun, Barista Kunle Oyatomi ti so pe afi eni ti ko ba loju, ti ko si ni eri okan tooto lo le so pe ko si iyato ninuu bipinle Osun se wa lasiko isejoba PDP si asiko yii.

Nigba to n fesi si oro awon egbe oselu PDP laipe yii pe awon yoo gbasejoba ipknle Osun pada lowo egbe oselu APC ninu idibo Gomina to n bo losu kesan odun yii.

Oyatomi ni ajanaku loro awon ise ribiribi ti Gomina Aregbesọla ti se nipinle Osun, o kojaa mo ri nnkan firi.

O ni awon ona tijoba PDP ko mojuto nogba ti won wa nibe ni won ti di apewaawo bayii. Awon ibi ti omiyale si ti n yo won lenu tele ni won ti kuro ni pakute iku nigba tijoba Aregbesola ti mu ayipada ba won.

Gege bo se wi , "Se ti Gbonmi ni abi Omigade, se awon eeyan agbegbe Rasco le gbagbe Aregbesola ti egbe kan ti ko le da ile ara won to yoo fi wa so pe awon yoo gbajoba l'Osun".

Oyatomi ni dipo kawon egbe PDP ti won ko le da idibo woodu lasan se laisi wahala loo yanju oro aye won, se ni won n fonnu kaakiri pe awon yoo gbajoba.

O waa ro awon araalu lati mase je ki ẹnikẹni ba ayo ati alaafia ti won ti n jegbadun re labe isakoso Aregbesọla je, ki won si je oju lalakan fi n sori lasiko idibo to n bo ohun.


No comments:

Post a Comment