Isejoba mi yoo so ipinle Osun di apewaawo lagbaye - Olaniyi Loye
Pelu bi awon oloselu se n mura sile lati joko lori aga gege bii gomina ipinle Osun leyin idibo osu kesan odun yii, oludije kan ti ro awon araalu lati dibo yan eni to ba lafojusun rere fun idagbasoke ipinle Osun.
Ogbeni Babatunde Olaniyi Loye ninu atejade kan ti akowe iroyin re fun Agbala Iroyin nilu Oṣogbo salaye pe omo alaso lawon eeyan ipinle Osun, ko ye ki won maa wo akisa.
Olaniyi ni oludije to ni ogbon inu lati sejoba lona to yato si bi won se n se e tele nipinle Osun nilo bayii, kii se awon to je pe bi awon kan se se loun naa a maa sejoba.
Okunrin oloselu yii ni, oun, gege bii eni to ti lamilaka nidi ise to yan laayo loke okun ti mo oniruuru ona lati le sejoba lona tawon araalu yoo fi gbagbe gbogbo iya ti won ti je seyin.
O ni oniruuru awon nnkan alumoni to le maa mowo wole labenu funjoba lo wa nipinle Osun, bakan naa loun yoo tun gbajumo ise agbe lona to je pe awon ara oke-okun gan an maa rogboku lejoba ipinle Osun fun ounje.
Olaniyi Loye ni oun yoo mu ayipada tooto ba isejoba nipinle Osun tawon araalu ba le fi ibo won gbe oun wole gege bii gomina ati pe aabo yoo wa fun emi ati dukia awon araalu gege bo se wa loke-okun.
Gege bo se wi, gbogbo iriri to ti ni nipa isakoso loke-okun lati odun 2001 to ti wa nibe yoo ran an lowo lati mu idagbasoke ti ko legbe bapinle Osun.
Subscribe to:
Post Comments (Atom)
No comments:
Post a Comment