Awon omo mi ni won so pe ki n feyawo tuntun - Baba Abiara




Ajihinrere apapo tele funjo Christ Apostolic Church (CAC) lagbaye, Efangelisi Samuel Kayode Abiara ti so pe awon omo oun ni won gba oun niyanju lati feyawo miin lati le toju oun lojo ogbo.

Baba Abiara, eni ti iyawo  re akooko jade laye lodun kan aabo seyin leyin ti won jo lo bii aadota odun gege bii lokolaya salaye pe leyin imoran awon omo oun loun gba odo Olorun lo, ti Olorun si tun fun oun nidari lati segbeyawo miin.

Laipe yii ni Baba Abiara segbeyawo pelu Arabinrin Grace Ojewande to je omobibi ilu Ifetedo nipinle Osun. Obinrin yii la gbo pe o ti le lomo aadota odun sugbon ti ko tii lọkọ tabi bimo kankan ri ko too fe Baba Abiara.

Ipele owo osu kẹrindinlogun nileese eto eko ipinle Eko  lo ti n sise, omo ijo Mountain of Fire and Miracles Ministry si ni ki won too segbeyawo alarinrin naa ninu ijo CAC Agbala Itura, Ibadan laipe yii.

Baba Abiara fi kun oro re pe Bibeli faaye gba enikeni tiyawo re ba ku lati feyawo miin, idi si niyen toun fi tele idari Olorun ati tawon omo oun lati gbe igbese toun gbe.

No comments:

Post a Comment