Esther Ajayi Foundation: Ajo to n mu omije kuro loju awon alaini

Lasiko yii to je pe gbogbo eeyan lo n sora lati soore, bee nijoba gan an ko setan lati tan osi awon araalu, iyalenu lo je lati ri ajo kan ti ko rogboku lejoba, to si n derin peeke awon eeyan kaakiri agbaye.






Ajo Esther Ajayi Foundation, gege bi oludasile re, Reverend Mother Esther Ajayi, to tun je Alakoso ijo Love of Christ Generation Church, UK se so wa lati mu inu awon eeyan dun nipase eyi ti aye yoo fi see gbe fun tolori-telemu.

Erongba ajo naa ni lati rii pe ise ati osi pare lawujo nipase nina ọwọ iranwo sawon eeyan kaakiri orileede Naijiria ati kaakiri orileede agbaye.

Oke aimoye oro-eri lawon eeyan n so lojoojumo nipa ajo yii, opolopo orileede ni won si ti de nibi ti won ti la ipa rere ninu aye awon olugbe ibe. Won ti na ọwọ iranwo de awon orileede bii Bulgaria, Isreal, Ghana, Nigeria, England, bee ni won n mura lati mi orileede USA titi laipe yii.

Ajo Esther Ajayi, lowolowo bayii, n mu ogunlogo eeyan kuro ninu aini, won n pese ile fawon alainile lori, won n da Ireti pada sokan awon onirobinuje, bakan naa ni won n tiraka lati fopin si ilokulo awon omode.

Ko tan sibe, awon obinrin ti ajo yii ti fi ise gidi to too gbo bukata idile ati eyi to to ran ọkọ lowo le lowo po yanturu, bee ni won ko gbeyin ninu awon igbese alaafia ni gbogbo ibi ti won ba de.

Ajo Esther Ajayi foundation tun n si awon eeyan niye kaakiri agbaye nipa ififunni eleyii ti won gbagbo pe yoo mu ki alaafia wa laarin awon araalu niwon igba ti ko ba ti si eni to salaini ohun to dara.

Idi niyen ti ajo naa fi wa n kesi awon ijoba, ileese aladani, ileese nlanla atawon ti Olorun bukun lawujo lati mase foju pa awon alaini re, ki won dide fun iranlowo elomiin, ki aye le rorun fun gbogbo eeyan.

Yato si awon oludokoowo ti ajo naa fun ni milioonu kookan naira lorileede Naijiria laipe yii, ajo naa tun ti mura, gege bi a se gbo, lati derin peeke awon eeyan lojo ayeye ojo-ibi Reverend Mother Esther Ajayi ti yoo waye lojo keji osu kerin yii,

No comments:

Post a Comment