Lobatan! Bayo Faforijin kede ojo ti yoo kuro ninu egbe oselu PDP

Alaga abala kan ninu egbe oselu PDP nipinle Osun, Dokita Bayo Faforijin ti ni lojo ti olu-ile egbe naa l'Abuja ba fonte lu abajade idibo abele tawon kan se nipinle yii lose to koja loun atawon alatileyin oun yoo dagbere fegbe naa.


Lasiko ti Faforijin n ba Agbala Iroyin soro lo salaye pe oun si wa ninu egbe PDP sugbon oun n duro de igbesẹ tawon igbimọ egbe labe isakoso Omooba Secondus yoo gbe nipa idibo naa.

Faforijin ni "Kii se bi a se n se egbe oselu wa niyen, ohun ti won se tako ofin egbe wa, ojoo fraide, sannde ati Tusde ni egbe fun won lase lati sedibo sugbon nitori eru ti won fee se, won se ni fraide, satide ati sannde.

"Awon ti won sese n darapọ mo egbe ni won n da wahala sile nitori jegudujera ni gbogbo won. Sugbon ti egbe l'Abuja ba ti le gba esi idibo yen wole, a je pe ko si nnkan ti mo n duro mu mo, n ko le wa ninu egbe ti ko si ibowo fun ofin ".

A o ranti pe lojoo sannde to koja lawon asoju egbe naa lati Abuja wa seto idibo nipinlẹ Osun ninu eyi ti Onorebu Soji Adagunodo ti jawe olubori gege bii alaga.

No comments:

Post a Comment