Aregbesọla seto oko-oju irin ofe fodun Ajinde

Lati le je ko rorun fawon eeyan ipinle Osun atawon ipinle to yii ka ti won n gbe nipinle Eko lati le waa sodun ajinde nile, Gomina Aregbesọla tun ti seto oko reluwee ofe fun won.


Gege bi atejade kan ti komisanna foro okoowo ati alajeseku nipinle Osun, Onorebu Ismaila Jayeoba Alagbada fowosi se so, eleyii ni yoo je ikerinlelogbon iru e tijoba ipinle Osun yoo seto e. 

Alagbada ni lati odun 2010 tijoba Aregbesola ti bere gbigbe awon eeyan pelu reluwee ofe lawon ayajo odun , yala odun keresimesi, Ileya, ajinde tabi itunu aawe.

O nl lati Ido Terminus mi Ebutte Metta ni oko reluwee naa yoo ti gbera logbonjo osu keta odun yii wa silu Oṣogbo laago mewa aaro.

Leyin odun ajinde, iyen ojo keji osu kerin odun yii ni reluwee ohun yoo pada silu Eko lati Oṣogbo.

Alagbada waa ro awon eeyan lati lo anfaani oko reluwe ofe, ti won pe ni Omoluabi Train naa lati wa sodun lodo awon molebi won nile.

O gbosuba funjoba Aregbesọla lori igbese re lati mu aye derun fawon araalu nitori pe eto oro aje ipinle Osun tun ti ru gọgọ sii latigba ti eto naa ti bere.

No comments:

Post a Comment