Stephen Uwa eni ogota odun ti wa lakolo ileese olopa ipinle Eko bayii lori esun pe obinrin abileko kan ti won jo n yan ara won lale ku sinu ile e.
O pe ti baba yii ati Joy Vincent ti n yan ara won lale, gege bi a se gbo, sugbon oro yiwo lojoo Sannde ti Joy lo silee Stephen to wa ni opopona Adeniji, ladugbo Iyana Ishashi.
Ko seni to mo nnkan to sele si Joy nile Stephen, oku re la gbo pe Stephen dogbon gbe pada sile to n gbe lagbegbe Osha Arigba ni Imude nilu Eko kannaa.
Iya alate kan to kofiri Stephen nigba to gbe oku Joy wole la gbo pe o ranse si omo obinrin naa, Ikechukwu to wa nileewe lati waa wo nnkan to se iya re.
Eleyi lo si je ki owo tete te Stephen, ti won si fa a le awon olopa lowo.
No comments:
Post a Comment