E wo Olalekan to sa awon omoleewe meji pa nipinle Ogun






Owo awon odo agbegbe ijoba ibile Ogun Waterside nipinle Ogun ti te okunrin alarun opolo to sa akeko meji pa lojo Monde to koja.



Se la gbo pe Lekan Adebisi sare wonu ileewe St John Anglican Primary School lagbegbe Agodo losan ojo naa lasiko tawon omo ohun fee jeun.

Ada nla to mu yanranyanran ti Lekan mu lowo la gbo pe o fi sa awon akeko meji naa pa, bo si ti sise owo re tan la gbo pe o juba ehoro.

Sugbon owo ti te okunrin naa bayii, won si ti fa a le awon olopa agbegbe naa lowo.

No comments:

Post a Comment