Lagbala iroyin la ti gbo pe adajo ile ejo giga kan nipinle Bayelsa, Onidajo Nayai Aganaba ti pase pe ki won loo yegi fun obinrin eni ogbon odun kan, Victoria Gagariga lori esun pe o pa oko re, Henry Gagariga.
Adajo Nayai so pe gbogbo eri to wa niwaju oun lo fidii re mule pe olujejo lo gun oko re lobe pa latari owu-jije to fa wahala laarin won lojo kerin osu keji odun 2015.
O ni pelu eleri mefa ti won jeri tako obinrin naa nile ejo, iwadi ti fidii re mule pe obinrin yii nikan lo wa ninu ile pelu oko re lojo isele naa ati pe obe lo fi gun un lorun ti iyen si gbabe ku lojo naa.
No comments:
Post a Comment